Skip to content
الأنبيَاء /

Ẹsẹ 91

21 : 91
الأنبيَاء Àwọn Ẹsẹ 112
21 : 91

وَٱلَّتِيٓ أَحۡصَنَتۡ فَرۡجَهَا فَنَفَخۡنَا فِيهَا مِن رُّوحِنَا وَجَعَلۡنَٰهَا وَٱبۡنَهَآ ءَايَةٗ لِّلۡعَٰلَمِينَ

(Ẹ rántí obìnrin) èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn nínú àwọn atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá sí i lára. A sì ṣe òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.

Explanation & meanings · 1
  1. Kíyè sí i! Ṣíṣe tí Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - ṣe Mọryam àti ọmọ rẹ̀, Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá, kò túmọ̀ sí pé ìkíní kejì wọn jẹ́ olúwa àti olùgbàlà.