Skip to content
الإسرَاء /

Ẹsẹ 60

17 : 60
الإسرَاء Àwọn Ẹsẹ 111
Súrà · الإسرَاء
Yorùbá · Mikail
17 : 60

وَإِذۡ قُلۡنَا لَكَ إِنَّ رَبَّكَ أَحَاطَ بِٱلنَّاسِۚ وَمَا جَعَلۡنَا ٱلرُّءۡيَا ٱلَّتِيٓ أَرَيۡنَٰكَ إِلَّا فِتۡنَةٗ لِّلنَّاسِ وَٱلشَّجَرَةَ ٱلۡمَلۡعُونَةَ فِي ٱلۡقُرۡءَانِۚ وَنُخَوِّفُهُمۡ فَمَا يَزِيدُهُمۡ إِلَّا طُغۡيَٰنٗا كَبِيرٗا

(Rántí) nígbà tí A sọ fún ọ pé: “Dájúdájú Olúwa rẹ yí àwọn ènìyàn po (pẹ̀lú agbára Rẹ̀). Àti pé A kò ṣe ìran (wíwò) tí A fi hàn ọ́ àti igi (zaƙūm) tí A ṣẹ́bi lé nínú al-Ƙur’ān ní kiní kan bí kò ṣe pé (ó jẹ́) àdánwò fún àwọn ènìyàn. À ń dẹ́rù bà wọ́n, àmọ́ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìwà àgbéré tó tóbi.

Explanation & meanings · 1
  1. Híhù tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - mú igi zaƙūm hù jáde láti inú Iná jẹ́ ohun tí ó tako òye àwọn aláìgbàgbọ́. Wọ́n takò ó. Àtakò wọn sì di àdánwò fún wọn.