Skip to content

“Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”.

Lati ọdọ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun mi pe:

“Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”.

«لَا تَحْقِرَنَّ مِنَ الْمَعْرُوفِ شَيْئًا، وَلَوْ أَنْ تَلْقَى أَخَاكَ بِوَجْهٍ طَلْقٍ».

Muslim ni ọ gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe wa ni ojúkòkòrò lori ṣíṣe dáadáa, ki èèyàn si ma fi oju kéré rẹ kódà ki o kéré, ninu ìyẹn ni tituju ka pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ nígbà tí a ba pade. O tọ́ fun Mùsùlùmí ki o ṣe ojúkòkòrò rẹ; tori ifi ara ro ọmọ-ìyá ti o jẹ Mùsùlùmí wa ninu ẹ, ati mimu ìdùnnú wọ inu rẹ̀.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ọla ti n bẹ fun ìfẹ́ láàrin àwọn onigbagbọ, ati ẹ̀rín-músẹ́ ati ìtújúká ti wọn ba pade.

Pípé sharia ati kikari rẹ, ati pe o wa pẹlu gbogbo nǹkan ti àǹfààní ba n bẹ nibẹ fun awọn Mùsùlùmí ati ṣíṣe wọn ní ọ̀kan.

Ṣiṣenilojukokoro lori ṣíṣe dáadáa kódà ki o kéré.

A fẹ ki a maa dun àwọn Musulumi ninu; tori pe ìyẹn maa jẹ ki ìfẹ́ o wa laarin wọn.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Muslim (4/ 2026) (2626).

(1/ 572).

Àlékún (7)

منحة العلام في شرح بلوغ المرام.

لعبد الله الفوزان (10/ 119).

توضيح الأحكام من بلوغ المرام.

للبسام (7/ 341).

نزهة المتقين شرح رياض الصالحين.

بهجة الناظرين شرح رياض الصالحين.

لسليم الهلالي (2/ 20).