"Dajudaju awọn eniyan ti wọn ba ti ri alabosi, ti wọn ko si gba a mu ni ọwọ rẹ mejeeji, o sunmọ ki Ọlọhun fi iya kan lati ọdọ Rẹ kari wọn".
Lati ọdọ Abu Bakr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo pe ẹyin eniyan, ẹ maa n ka aayah yìí: (Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀na), mo si gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
"Dajudaju awọn eniyan ti wọn ba ti ri alabosi, ti wọn ko si gba a mu ni ọwọ rẹ mejeeji, o sunmọ ki Ọlọhun fi iya kan lati ọdọ Rẹ kari wọn".
«إِنَّ النَّاسَ إِذَا رَأَوْا الظَّالِمَ فَلَمْ يَأْخُذُوا عَلَى يَدَيْهِ أَوْشَكَ أَنْ يَعُمَّهُمُ اللَّهُ بِعِقَابٍ مِنْهُ».
Abu Bakr As-Sideeq- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe: Dajudaju awọn eniyan a maa ka aayah yìí: (Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀na)(Al-Maa'ida: 105). Ti wọn maa wa gbọye ninu rẹ pe dajudaju igbiyanju jẹ dandan lori ọmọniyan lori titun ara rẹ ṣe nikan, ati pe ìṣìnà ẹni ti o ṣina ko nii ko inira ba a lẹyin ìyẹn, ati pe wọn ko wa lati ọdọ wọn pipáṣẹ daadaa ati kikọ iwa ibajẹ! ni o wa fi mọ wọn pe ko ri bayẹn, pe oun gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa a- n sọ pe: Dajudaju awọn eniyan ti wọn ba ti ri alabosi ti wọn ko si kọ fun un kuro nibi abosi ṣíṣe rẹ, ti agbara lori kikọ fun un si n bẹ lọdọ wọn, ó maa ku díẹ̀ ki Ọlọhun fi iya kan lati ọdọ Rẹ kari gbogbo wọn, ẹni ti o n ṣe ibajẹ ati ẹni ti o n dakẹ nipa rẹ.
Ojúṣe awọn Musulumi ni gbigba ara wọn ni imọran, ati pipaṣẹ daadaa ati kikọ ibajẹ.
Iya Ọlọhun ti gbogboogbo maa kari alabosi fun ṣíṣe abosi rẹ, o si maa kan ẹni ti o dakẹ lori titako o ti o si ni ikapa lori titako o.
Kikọ gbogbo eniyan ati imu wọn gbọ́ awọn aayah Kuraani ye ni ọna ti o ni alaafia ti o wa fun wọn.
Àbójútó jẹ dandan fun ọmọniyan lati ni agbọye iwe Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-, ti ko fi nii gbọ ọ ye ni ọna ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko gba lero.
Imọna ko nii ṣẹlẹ̀ pẹlu gbigbe pipaṣẹ daadaa ati kikọ ibajẹ silẹ.
Alaye ti ó tọna fun aayah náà ni: Ẹ dunni mọ sisọ ẹmi ara yin kuro nibi awọn ẹṣẹ, ti ẹ ba ti sọ ẹmi ara yin, anù ẹni ti o ba sọnu ko nii ko inira ba yin ti ẹ ko ba ni ikapa lati pàṣẹ daadaa ati lati kọ ibajẹ, pẹlu ṣíṣe awọn nnkan èèwọ̀ ti ẹ ba ti mọna lọ sibi jijina si i.
Tira Sunanu ti Tirmidhiy (4/ 40) (2168).
Tira Sunanu ti baba Daud (6/ 393) (4338).
Tira As-Sunanul Kubrọ ti An-Nasaaiy (10/ 88) (11092).
Tira Sunanu ti Ọmọ Maajah (5/ 139) (4005).
Tira Musnad ti Ahmad (1/ 197) (16).
Àlékún (8)
بهجة الناظرين شرح رياض الصالحين.
لسليم الهلالي (1/ 286).
كنوز رياض الصالحين.
مجموعة من الباحثين (4/ 126).
شرح رياض الصالحين.
لابن عثيمين (2/ 454).
نزهة المتقين شرح رياض الصالحين.
لمجموعة من الباحثين (1/ 218).
A tọ́ka sí nínú àwọn ìwé
3 Àwọn ÌwéÀlékún (3)
- رياض الصالحينرياض الصالحين مع فوائد وهدايات - 2«إنَّ النَّاسَ إذَا رَأوُا الظَّالِمَ، فَلَمْ يَأْخُذُوا عَلَىٰ يَدَيْهِ أَوْشَكَ أَنْ يَعُمَّهُمُ اللهُ بِعِقَابٍ مِنْهُ».
- قاموس الكبائرموسوعة الكبائر - المجموعة الثانية«إِنَّ النَّاسَ إِذَا رَأَوْا ظَالِمًا، فَلَمْ يَأْخُذُوا عَلَى يَدَيْهِ أَوْشَكَ أَنْ يَعُمَّهُمُ اللَّهُ بِعِقَابٍ مِنْهُ» [145].
- نبراس طالب (2)نبراس طالب (2) «إِنَّ النَّاسَ إِذَا رَأَوْا ظَالِمًا، فَلَمْ يَأْخُذُوا عَلَى يَدَيْهِ أَوْشَكَ أَنْ يَعُمَّهُمُ اللَّهُ بِعِقَابٍ مِنْهُ»