Skip to content

“Ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí ó kọ́ Kuraani ti o si tun kọ́ ẹlòmíràn”.

Lati ọdọ Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:

“Ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí ó kọ́ Kuraani ti o si tun kọ́ ẹlòmíràn”.

«خَيْرُكُمْ مَنْ تَعَلَّمَ الْقُرْآنَ وَعَلَّمَهُ».

Bukhaariy lọ gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fún wa pe ẹni ti o ni ọlá ju ninu awọn Mùsùlùmí ti o si tun ga ju ni ipo ni ọdọ Ọlọhun ni: Ẹni ti o ba kọ́ Kuraani, ni kika ati hiha, ati kike e ni pẹlẹpẹlẹ, ati agbọye rẹ, ati itumọ rẹ, ti o tun wa kọ́ ẹlòmíràn ni ohun ti n bẹ lọdọ rẹ ninu imọ Kuraani pẹlu lílò ó.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Àlàyé iyì Kuraani, ati pe oun ni ọ̀rọ̀ ti o loore ju; tori pe ọ̀rọ̀ Ọlọhun ni.

Ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn akẹ́kọ̀ọ́ ni ẹni tí n kọ́ ẹlòmíràn, kii ṣe ẹni tí ó fi mọ lori ara rẹ nìkan.

Kíkọ́ Kuraani, ati kikọ ẹlòmíràn ni Kuraani kó kike e ati awọn ìtumọ̀, ati awọn idajọ sinu.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (6/ 192) (5027).

Àlékún (8)

فتح الباري شرح صحيح البخاري.

لابن حجر العسقلاني (1/ 374).

بهجة الناظرين شرح رياض الصالحين.

لسليم الهلالي (2/ 226).

نزهة المتقين شرح رياض الصالحين.

لمصطفى الخن وغيره (1/ 740).

شرح رياض الصالحين.

لابن عثيمين (4/ 638).