5 : 71
وَحَسِبُوٓاْ أَلَّا تَكُونَ فِتۡنَةٞ فَعَمُواْ وَصَمُّواْ ثُمَّ تَابَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡ ثُمَّ عَمُواْ وَصَمُّواْ كَثِيرٞ مِّنۡهُمۡۚ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِمَا يَعۡمَلُونَ
Wọ́n sì lérò pé kò níí sí ìfòòró; wọ́n fọ́jú, wọ́n sì dití (sí òdodo). Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n fọ́jú, wọ́n tún dití (sí òdodo); ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn (ló ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Explanation & meanings · 1
- Ìyẹn ni pé, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lérò pé, àwọn lè máa dẹ́sẹ̀ lọ láì níí ronú pìwàdà, kò sì níí sí wàhálà àti ìyà fún àwọn láyé àti lọ́run.