5 : 26
قَالَ فَإِنَّهَا مُحَرَّمَةٌ عَلَيۡهِمۡۛ أَرۡبَعِينَ سَنَةٗۛ يَتِيهُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ فَلَا تَأۡسَ عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡفَٰسِقِينَ
(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ó ti di èèwọ̀ fún wọn (láti wọnú ìlú náà) fún ogójì ọdún tí wọn yóò fi rin àrìnnù lórí ilẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
Explanation & meanings · 1
- Ànábì Mūsā àti arákùnrin rẹ̀ Hārūn - kí ọlà Allāhu máa bá àwọn méjèèjì - kú sórí ìrìn-àjò ológójì ọdún náà. Ànábì Yūṣa‘ - kí ọlà Allāhu máa bá a - ló padà darí wọn wọnú ìlú náà.