5 : 25
قَالَ رَبِّ إِنِّي لَآ أَمۡلِكُ إِلَّا نَفۡسِي وَأَخِيۖ فَٱفۡرُقۡ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡفَٰسِقِينَ
Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ẹnì kan bí kò ṣe (lórí) ara mi àti arákùnrin mi. Nítorí náà, ya àwa àti ìjọ òbìlẹ̀jẹ́ sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”
Explanation & meanings · 1
- Ìyẹn ni pé, bí Allāhu bá fẹ́ fi ìyapa-àṣẹ tí wọ́n ṣe gbá wọn mú, má ṣe jẹ wá ní ìyà pẹ̀lú wọn. Àwọn ni wọ́n yapa àsẹ Rẹ, kì í ṣe àwa.