Skip to content
المَائدة /

Ẹsẹ 107

5 : 107

Ẹsẹ 107 of المَائدة (5 : 107). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

المَائدة Àwọn Ẹsẹ 120
Súrà · المَائدة
Yorùbá · Mikail
5 : 107

فَإِنۡ عُثِرَ عَلَىٰٓ أَنَّهُمَا ٱسۡتَحَقَّآ إِثۡمٗا فَـَٔاخَرَانِ يَقُومَانِ مَقَامَهُمَا مِنَ ٱلَّذِينَ ٱسۡتَحَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡأَوۡلَيَٰنِ فَيُقۡسِمَانِ بِٱللَّهِ لَشَهَٰدَتُنَآ أَحَقُّ مِن شَهَٰدَتِهِمَا وَمَا ٱعۡتَدَيۡنَآ إِنَّآ إِذٗا لَّمِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ

Tí wọ́n bá sì mọ̀ pé àwọn méjèèjì dá ẹ̀ṣẹ̀ (nípa yíyí àsọọ́lẹ̀ padà tàbí jíjí dúkìá aláìsí), kí àwọn méjì mìíràn nínú ẹbí òkú tí àsọọ́lẹ̀ lẹ́tọ̀ọ́ sì jùlọ, (ìyẹn) ènìyàn méjì tí ó súnmọ́ òkú jùlọ rọ́pò àwọn méjèèjì àkọ́kọ́ (níbi mímú àsọọ́lẹ̀ mìíràn wá fún òkú). Kí àwọn náà sì fi Allāhu búra pé: “Dájúdájú ẹ̀rí jíjẹ́ tiwa jẹ́ òdodo ju ẹ̀rí jíjẹ́ ti àwọn méjèèjì (àkọ́kọ́). A ò sì níí tayọ ẹnu-ààlà. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú a ti wà nínú àwọn alábòsí.”

Explanation & meanings · 1
  1. Tàbí “kí àwọn méjì mìíràn nínú ẹbí òkú tí wọ́n lè da ẹrí jíjẹ́ àwọn méjèèjì àkọ́kọ́ nù”.