5 : 108
ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَن يَأۡتُواْ بِٱلشَّهَٰدَةِ عَلَىٰ وَجۡهِهَآ أَوۡ يَخَافُوٓاْ أَن تُرَدَّ أَيۡمَٰنُۢ بَعۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱسۡمَعُواْۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ
Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti mú ẹ̀rí jíjẹ́ wá ní ojú-pọ̀nnà rẹ̀ tàbí láti (lè là nínú) ìpáyà pé wọ́n yóò da ìbúra kan nù (ìbúra ẹni méjì àkọ́kọ́) lẹ́yìn ìbúra tiwọn (ìbúrà ẹni méjì kejì). Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gbọ́ràn. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
Explanation & meanings · 1
- Òfin yìí, òfin àsọọ́lẹ̀ lórí ogún, igun kan nínú àwọn onímọ̀ sọ pé, wọ́n ti pa ìdájọ́ rẹ̀ rẹ́, àmọ́ igun kejì sọ pé, wọn kò pa ìdájọ́ rẹ̀ rẹ́.