34 : 13
يَعۡمَلُونَ لَهُۥ مَا يَشَآءُ مِن مَّحَٰرِيبَ وَتَمَٰثِيلَ وَجِفَانٖ كَٱلۡجَوَابِ وَقُدُورٖ رَّاسِيَٰتٍۚ ٱعۡمَلُوٓاْ ءَالَ دَاوُۥدَ شُكۡرٗاۚ وَقَلِيلٞ مِّنۡ عِبَادِيَ ٱلشَّكُورُ
Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ tí ó bá fẹ́ fún un nípa mímọ àwọn ilé (ilé ìjọ́sìn àti ilé ìgbé), àwọn ère, àwọn àwo tó jìn kòtò tó fẹ̀ bí àbàtà àti àwọn ìkòkò tó rídìí múlẹ̀. Ẹ̀yin ènìyàn (Ànábì) Dāwūd, ẹ ṣiṣẹ́ ìdúpẹ́ (fún Allāhu). Díẹ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Mi sì ni olùdúpẹ́.
Explanation & meanings · 3
- Ní àsìkò Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a -, gbígbẹ́ ère fún fífi ṣe ọ̀ṣọ́ sínú ilé kì í ṣe èèwọ̀. Àmọ́ ní àsìkò Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó ti di èèwọ̀, yálà ó jẹ́ ère tàbí àwòrán n̄ǹkan abẹ̀mí.
- Àpẹ̀ẹrẹ ìyẹn ni àwọn àwo tí àwọn ènìyàn máa ń ṣe sínú ilé ìwẹ̀ tí ènìyàn máa ń wẹ̀ nínú rẹ̀ “bath tub”.
- Àpẹ̀ẹrẹ ìyẹn ni àwọn apẹ irin ìdáná ńlá ńlá.