28 : 78
قَالَ إِنَّمَآ أُوتِيتُهُۥ عَلَىٰ عِلۡمٍ عِندِيٓۚ أَوَلَمۡ يَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ قَدۡ أَهۡلَكَ مِن قَبۡلِهِۦ مِنَ ٱلۡقُرُونِ مَنۡ هُوَ أَشَدُّ مِنۡهُ قُوَّةٗ وَأَكۡثَرُ جَمۡعٗاۚ وَلَا يُسۡـَٔلُ عَن ذُنُوبِهِمُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ
Ó wí pé: “Dájúdájú wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ tó ń bẹ lọ́dọ̀ mi ni.” Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ti parun nínú àwọn ìran tó ṣíwájú rẹ̀, ẹni tí ó lágbára jù ú lọ, tí ó sì ní àkójọ ọrọ̀ jù ú lọ? A ò sì níí bi àwọn arúfin léèrè (ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó kúkú ti wà ní àkọsílẹ̀.)
Explanation & meanings · 1
- Ìyẹn ni pé, òun mọ̀ ọ́ ṣe ni ti tòun fi gún. Dípò kí ó moore sí Allāhu, kí ó dúpẹ́ fún Un, kí ó sì mọ̀ pé Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún un ni nínú kádàrá Rẹ̀.