Skip to content

"Dajudaju aye jẹ nnkan ti o dun ti o si tutu, ati pe dajudaju Ọlọhun n fi yin ṣe arole nibẹ, ti yoo maa wo nnkan ti ẹ ń ṣe, ẹ bẹru aye ki ẹ si bẹru obinrin

Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:

"Dajudaju aye jẹ nnkan ti o dun ti o si tutu, ati pe dajudaju Ọlọhun n fi yin ṣe arole nibẹ, ti yoo maa wo nnkan ti ẹ ń ṣe, ẹ bẹru aye ki ẹ si bẹru obinrin, dajudaju akọkọ fitina awọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ lara obinrin".

«إِنَّ الدُّنْيَا حُلْوَةٌ خَضِرَةٌ، وَإِنَّ اللهَ مُسْتَخْلِفُكُمْ فِيهَا، فَيَنْظُرُ كَيْفَ تَعْمَلُونَ، فَاتَّقُوا الدُّنْيَا وَاتَّقُوا النِّسَاءَ، فَإِنَّ أَوَّلَ فِتْنَةِ بَنِي إِسْرَائِيلَ كَانَتْ فِي النِّسَاءِ».

Muslim ni ọ gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju aye dun nibi itọwo, o si tutu nibi riri, ti ọmọniyan maa gba ẹtanjẹ pẹlu rẹ ti yoo si tẹ̀rì sinu rẹ ti yoo si sọ ọ di eyi ti o tobi julọ ninu ironu rẹ. Ati pe dajudaju Ọlọhun- mimọ ni fun Un- fi awọn kan ninu wa role fun awọn kan ni igbesi aye yìí, ki O le maa wo bi a ṣe maa ṣiṣẹ, njẹ a maa tẹle E, tabi a maa yapa Rẹ? Lẹyin naa, o sọ pe: Ẹ ṣọ́ra ki igbadun aye ati ọṣọ rẹ ma tan yin jẹ, ti o wa maa mu yin gbe nnkan ti Ọlọhun pa yin láṣẹ rẹ ju silẹ, ati kiko si nnkan ti O kọ kuro fun yin nibẹ. Ati pe ninu nnkan ti o jẹ dandan julọ lati ṣọ́ra kuro ninu rẹ ninu awọn wahala aye ni wahala obinrin, ati pe o jẹ akọkọ wahala ti awọn ọmọ Ísírẹ́lì ko síbẹ̀.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

خَضِرَة: غضة ناعمة طرية. فالدنيا تُشبِه في الميل إليها الفاكهة الحلوة الطرية في مذاقها، الخضرة في لونها.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ṣisẹnilojukokoro lori idunnimọ ibẹru, ati aiko akolekan pẹlu awọn nnkan adun aye ati ọṣọ rẹ.

Ikilọ kuro nibi fitina obinrin, ninu wiwo tabi fifi ọwọ́ dẹngẹrẹ mú iropọ wọn pẹlu awọn ọkunrin ajoji, tabi eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn.

Fitina obinrin wa ninu eyi ti o tobi julọ ninu awọn fitina ni aye.

Gbigba waasu ati gbigba ariwoye mu lara awọn ijọ ìṣáájú, ati pe nnkan ti o ṣẹlẹ̀ si awọn ọmọ Ísírẹ́lì le ṣẹlẹ̀ si awọn ti wọn yàtọ̀ si wọn.

Fitina obinrin ti o ba jẹ iyawo, o le la bọ ọkùnrin lọrun ninu inawo ni nnkan ti ko lagbara rẹ, ti yoo wa ko airoju ba a lati wa awọn àlámọ̀rí ẹsin, ti yoo ti i lọ sibi fifi ẹmi ara rẹ̀ wéwu lori wiwa ayé, ti obinrin naa ba jẹ ajoji, fitina rẹ ni fifa oju awọn ọkunrin mọra ati iko iyẹgẹrẹ ba wọn kuro nibi ododo ti wọn ba ti jade ti wọn ba si ti ropọ mọ wọn, pàtàkì julọ ti wọn ba jẹ obinrin ti wọn kò bo ojú ti wọn si ṣira silẹ, eleyii le ja si ṣìná pẹlu awọn ipele rẹ, o wa tọ fun olugbagbọ lati dirọ mọ Ọlọhun, ati ifi erongba han si I nibi igbala kuro nibi wahala wọn.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Muslim (4/ 2098) (2742).

Àlékún (6)

بهجة الناظرين شرح رياض الصالحين.

لسليم الهلالي (1/ 146).

كنوز رياض الصالحين.

لمجموعة من الباحثين (2/ 173).

نزهة المتقين شرح رياض الصالحين.

لمجموعة من الباحثين (1/ 103).