“Ẹni ti o ba sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOHU, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ ti jẹ eewọ, ati pe ìṣirò rẹ wa lọ́wọ́ Ọlọhun”.
Lati ọdọ Tooriq ọmọ Ashyam Al-Ash-ja'iy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
“Ẹni ti o ba sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOHU, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ ti jẹ eewọ, ati pe ìṣirò rẹ wa lọ́wọ́ Ọlọhun”.
«مَنْ قَالَ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، وَكَفَرَ بِمَا يُعْبَدُ مِنْ دُونِ اللهِ حَرُمَ مَالُهُ وَدَمُهُ، وَحِسَابُهُ عَلَى اللهِ».
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba sọ ti o si jẹrii pẹlu ahọn rẹ pe “LAA ILAAHA ILLALLOHU”, o n túmọ̀ si pe: Ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ afi Ọlọhun, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn jọsin fun yatọ si Ọlọhun, ti o bọpa-bọsẹ kuro nibi gbogbo awọn ẹsin yatọ si Isilaamu, dajudaju dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ jẹ eewọ fun awọn Musulumi, ohun ti ó kàn wa ni eyi ti o han ninu iṣẹ rẹ, wọn ko nii gba dukia rẹ, wọn ko si nii ta ẹjẹ rẹ silẹ, afi ti o ba da ẹṣẹ kan tabi wuwa ọdanran kan ti o maa sọ ìyẹn di dandan ni ìbámu si awọn idajọ Isilaamu. Ati pe Ọlọhun ni yoo ṣe ìṣirò rẹ ni ọjọ igbedide, ti o ba jẹ olododo yoo san an lẹsan, ti o ba jẹ sọbẹ-selu yoo fi iya jẹ ẹ.
...:
Sisọ LAA ILAAHA ILLALLOHU, ati ṣíṣe aigbagbọ pẹlu gbogbo nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, jẹ majẹmu nibi wiwọ inu Isilaamu.
Itumọ (LAA ILAAHA ILLALLOHU) ni ṣíṣe aigbagbọ pẹlu gbogbo nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun ninu awọn oosa ati awọn sàréè ati nnkan ti o yatọ si wọn, ati mimu U- mimọ ni fun Un- ni Ọkan ṣoṣo pẹlu ijọsin.
Ẹni ti o ba mu ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan wa ti o si dunni mọ awọn ofin rẹ ni ti gbangba, ikoraro kuro fun un jẹ dandan titi ti nnkan ti o yatọ si ìyẹn yoo fi han lati ọdọ rẹ.
Jijẹ eewọ dukia Musulumi ati ẹjẹ rẹ ati iyì rẹ afi pẹlu ẹtọ.
Idajọ ni aye wa lori nǹkan ti o ba hàn, o si wa lori awọn aniyan ati awọn erongba ni ọrun.
Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 53) (23).
Àlékún (4)
الملخص في شرح كتاب التوحيد.
لصالح الفوزان (ص68).
الجديد في شرح كتاب التوحيد.
لمحمد القرعاوي (ص77).
A tọ́ka sí nínú àwọn ìwé
3 Àwọn ÌwéÀlékún (3)
- التوحيد في ضوء عقيدة الإمام الشافعي رحمه الله ونصوصه ومروياته"من قال: لا إله إلا الله، وكفر بما يعبد من دون الله حرم ماله ودمه، وحسابه على الله ".([12])
- رياض الصالحينرياض الصالحين مع فوائد وهدايات - 2«مَن قال لا إلهَ إلَّا الله، وكَفَرَ بِمَا يُعْـبَـدُ مِنْ دُونِ الله، حَرُمَ مَالُهُ وَدَمُهُ، وَحِسَابُهُ عَلىٰ الله تعالىٰ».
- مشروع المنهج التعليميمادة التوحيد مستوى 1«مَنْ قَالَ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، وَكَفَرَ بِمَا يُعْبَدُ مَنْ دُونِ اللهِ؛ حَرُمَ مَالُهُ، وَدَمُهُ»