Skip to content

“Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”.

Lati ọdọ Saalim ọmọ Abul Jahd, o sọ pe: Arakunrin kan sọ pé: Ìbá ṣe pé mo ti kírun kí n sì sinmi, bí ẹni pé wọ́n dá a lẹ́bi fún ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:

“Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”.

«يا بلالُ، أقِمِ الصَّلاةَ، أرِحْنا بها».

Baba Daud ni o gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Arakunrin kan ninu awọn saabe sọ pe: Ìbá ṣe pé mo ti kírun ni, kí n sì sinmi, ó dà bíi pé àwọn tó wà láyìíká rẹ̀ dá a lẹ́bi lórí ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: Irẹ Bilal! Pe irun, ki o si gbe e dúró; ki a le sinmi pẹlu rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ fun nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu biba Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọrọ ni jẹẹjẹ, ati isinmi fun ẹmi ati ọkan.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Isinmi ọkan maa n wa pẹlu irun kiki; fun nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu biba Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọrọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.

Titako ẹni ti o pa ijọsin tì.

Ẹni ti o ba pe nnkan ti o jẹ dandan fun un, ti o si mọ ọrun rẹ kúrò nibẹ, isinmi maa ṣẹlẹ̀ si i pẹlu rẹ ati níní ìmọ̀lára ifayabalẹ.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sunanu ti baba Daud (7/ 338) (4985).

Àlékún (4)

الكاشف عن حقائق السُّنن (4/1217).

عون المعبود وحاشية ابن القيم (13/ 225).

مرقاة المفاتيح (3/939).

شرح سنن أبي داود للعباد (567/ 6).