Skip to content

“Dájúdájú èèyàn ti Ọlọhun koriira jù ni alátakò ti o le julọ”.

Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé:

“Dájúdájú èèyàn ti Ọlọhun koriira jù ni alátakò ti o le julọ”.

«إِنَّ أَبْغَضَ الرِّجَالِ إِلَى اللهِ الْأَلَدُّ الْخَصِمُ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga n koriira ninu awọn èèyàn ẹni ti o le ni àtakò ti o si maa n sáábà ṣe àtakò, ẹni tí kii tẹrí ba fun òdodo, ti o maa n gbìyànjú láti da a pada pẹlu iyàn jíjà rẹ, tabi ki o maa ṣe àtakò lori ododo, ṣùgbọ́n o maa ki aṣeju bọ̀ ọ́, o tun maa ṣe àtakò láìní imọ.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ki ẹni tí a ṣe àbòsí si beere ẹtọ rẹ nípasẹ̀ gbigbe ẹjọ́ lọ ba adajọ ti o ba òfin mu, eleyii kò kó sinu àtakò ti ko dára.

Ìjiyàn ati àtakò wa ninu awọn ìpalára ahọn ti o maa n ṣe okùnfà ìpín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ati ìkọ̀yìn-sí-ara-ẹni láàrin àwọn Musulumi.

Àtakò ti o dara ni eyi ti o ba jẹ nibi òdodo, ti ọ̀nà ti a gbe e gba naa si dára, o si maa jẹ eyi ti ko dára ti o ba wa fun dida òdodo padà, ati fifi irọ́ rinlẹ, tabi ki o ma si ẹ̀rí kankan fun un.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (3/ 131) (2457).

Tira Sọhiihu ti Muslim (4/ 2054) (2668).

Àlékún (8)

توضيح الأحكام من بلوغ المرام.

للبسام (7/ 476).

منحة العلام في شرح بلوغ المرام.

لعبد الله الفوزان (10/ 308).

فتح ذي الجلال والإكرام.

لابن عثيمين (6/ 416).

سبل السلام بشرح بلوغ المرام.

للصنعاني (2/ 685).