Skip to content

"Awọn alakatakiti ti parun

Lati ọdọ Abdullah ọmọ Mas'ud ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pé:

"Awọn alakatakiti ti parun " ó sọ bẹẹ ni ẹẹmẹta.

«هلك المُتَنَطِّعُون» قالها ثلاثًا.

Muslim ni ọ gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fún wa niroo nipa ìpòfo ati ipadanu awọn onilekoko - laisi ìmọ̀nà ati ìmọ̀ - ninu ẹsin ati igbesi aye wọn, ati ninu awọn ọrọ wọn ati awọn iṣẹ wọn, awọn tí wọ́n máa ń tayọ aala ofin sharia tí Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - mú wá fún wa.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

....:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Eewọ ni ilekoko ati tipátipá ninu gbogbo nkan, kí a sì gbiyanju lati jina si mejeeji ninu ohun gbogbo; paapaa julọ ninu awọn ijọsin wa ati igbe-titobi fun awọn ẹnirere.

Wíwá lati ṣe ijọsin ati awọn ohun miiran ní pípé jẹ́ nkan dáadáa; ó sì ni lati jẹ́ pẹlu titẹle ofin sharia.

Wọ́n fẹ́ kí a maa tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ pataki, nitori pé Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tún gbolohun yii sọ ni ẹẹmẹta.

Ìrọ̀rùn ẹ̀sìn Islam ati àilekoko rẹ̀.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Muslim (4/ 2055) (2670).

Àlékún (4)

الجديد في شرح كتاب التوحيد.

للقرعاوي (ص180).

الملخص في شرح كتاب التوحيد.

لصالح الفوزان (ص167).