Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

البَينَة

البَينَة is chapter 98 of the Quran and has 8 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

8 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 98
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

لَمۡ يَكُنِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ وَٱلۡمُشۡرِكِينَ مُنفَكِّينَ حَتَّىٰ تَأۡتِيَهُمُ ٱلۡبَيِّنَةُ

Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn kò níí kúrò nínú àìgbàgbọ́ wọn títí di ìgbà tí ẹ̀rí tó yanjú yó fi máa dé ọ̀dọ̀ wọn.

رَسُولٞ مِّنَ ٱللَّهِ يَتۡلُواْ صُحُفٗا مُّطَهَّرَةٗ

Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu yó (sì) máa ké àwọn tákàdá mímọ́.

فِيهَا كُتُبٞ قَيِّمَةٞ

Àwọn ìwé òfin tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ sì wà nínú rẹ̀.

وَمَا تَفَرَّقَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡبَيِّنَةُ

Àwọn tí A fún ní tírà kò sì di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ẹ̀rí tó yanjú dé bá wọn.

وَمَآ أُمِرُوٓاْ إِلَّا لِيَعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ حُنَفَآءَ وَيُقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤۡتُواْ ٱلزَّكَوٰةَۚ وَذَٰلِكَ دِينُ ٱلۡقَيِّمَةِ

Àwa kò sì pa wọ́n ní àṣẹ kan bí kò ṣe pé kí wọ́n jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn fún Un, lẹ́ni tí yóò dúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn. Kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì yọ Zakāh. Ìyẹn sì ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Al-’a‘rọ̄f 7:29.