Skip to content
التوبَة /

Ẹsẹ 94

9 : 94

Ẹsẹ 94 of التوبَة (9 : 94). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

التوبَة Àwọn Ẹsẹ 129
Súrà · التوبَة
Yorùbá · Mikail
9 : 94

يَعۡتَذِرُونَ إِلَيۡكُمۡ إِذَا رَجَعۡتُمۡ إِلَيۡهِمۡۚ قُل لَّا تَعۡتَذِرُواْ لَن نُّؤۡمِنَ لَكُمۡ قَدۡ نَبَّأَنَا ٱللَّهُ مِنۡ أَخۡبَارِكُمۡۚ وَسَيَرَى ٱللَّهُ عَمَلَكُمۡ وَرَسُولُهُۥ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَىٰ عَٰلِمِ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ

Wọ́n yóò mú àwáwí wá fún yín nígbà tí ẹ bá dé bá wọn nílé. Sọ pé: "Ẹ má ṣe mú àwáwí wá; a ò níí gbà yín gbọ́. Allāhu kúkú ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yín fún wa. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ yó sì rí iṣẹ́ (ọwọ́) yín. Lẹ́yìn náà, A óò da yín padà sí ọ̀dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nígbà náà, Ó máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Explanation & meanings · 1
  1. Āyah yìí jọ āyah 105 níwájú nínú sūrah yìí. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Āli ‘Imrọ̄n; 3:101 àti sūrah an-Nisā’; 4:64.