Skip to content
التوبَة /

Ẹsẹ 115

9 : 115
التوبَة Àwọn Ẹsẹ 129
Súrà · التوبَة
Yorùbá · Mikail
9 : 115

وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُضِلَّ قَوۡمَۢا بَعۡدَ إِذۡ هَدَىٰهُمۡ حَتَّىٰ يُبَيِّنَ لَهُم مَّا يَتَّقُونَۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٌ

Allāhu kì í mú ìṣìnà bá ìjọ kan, lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti tọ́ wọn sọ́nà, títí (Allāhu) yóò fi ṣe àlàyé n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣọ́ra fún fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

Explanation & meanings · 1
  1. Ìyẹn ni pé, à ò níí pe mùsùlùmí ní olùṣìnà bí ó bá ṣe n̄ǹkan tí kò yẹ kí ó ṣe níwọ̀n ìgbà tí kò ì sí ẹ̀rí kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu tí ó ṣe é ní èèwọ̀ fún un àfi lẹ́yìn ìgbà tí ẹ̀rí bá dé bá a, tí ó tún wá ń ṣe n̄ǹkan náà lọ.