6 : 14
قُلۡ أَغَيۡرَ ٱللَّهِ أَتَّخِذُ وَلِيّٗا فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَهُوَ يُطۡعِمُ وَلَا يُطۡعَمُۗ قُلۡ إِنِّيٓ أُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ أَوَّلَ مَنۡ أَسۡلَمَۖ وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ
Sọ pé: “Ṣé kí n̄g mú olùrànlọ́wọ́ kan yàtọ̀ sí Allāhu, Ẹlẹ́dàá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Òun sì ni Ó ń bọ́ (ẹ̀dá), wọn kì í bọ́ Ọ.” Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n pa mí láṣẹ pé kí n̄g jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣe ’Islām (ní àsìkò tèmi).” Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Explanation & meanings · 1
- Ìyẹn nínú ìjọ rẹ̀ torí pé gbogbo ànábì ló bá Islām nílé ayé.