5 : 23
قَالَ رَجُلَانِ مِنَ ٱلَّذِينَ يَخَافُونَ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمَا ٱدۡخُلُواْ عَلَيۡهِمُ ٱلۡبَابَ فَإِذَا دَخَلۡتُمُوهُ فَإِنَّكُمۡ غَٰلِبُونَۚ وَعَلَى ٱللَّهِ فَتَوَكَّلُوٓاْ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ
Àwọn ọkùnrin méjì kan nínú àwọn tí ń páyà (Allāhu) - Allāhu sì kẹ́ àwọn méjèèjì - wọ́n sọ pé: “Ẹ gba ẹnu bodè wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n. Tí ẹ bá wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n, dájúdájú ẹ máa borí wọn. Allāhu sì ni kí ẹ gbáralé, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”
Explanation & meanings · 1
- Allāhu ṣe ìtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀ ní ìrọ̀rùn fún àwọn méjèèjì. Èyí ni ìkẹ́ Allāhu lórí àwọn méjèèjì.