4 : 105
إِنَّآ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ لِتَحۡكُمَ بَيۡنَ ٱلنَّاسِ بِمَآ أَرَىٰكَ ٱللَّهُۚ وَلَا تَكُن لِّلۡخَآئِنِينَ خَصِيمٗا
Dájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí kí o lè máa ṣèdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn pẹ̀lú ohun tí Allāhu fi hàn ọ́. Má ṣe jẹ́ olùgbèjà fún àwọn oníjàǹbá.
Explanation & meanings · 1
- Kí ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ agbẹjọ́rò má ṣe jẹ́ ẹni tí yóò máa kọ́ ọ̀daràn ní irọ́ nítorí kí ó lè móríbọ́ nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Kí ẹ̀yin adájọ́ náà má ṣe dá ọ̀daràn láre.