Skip to content
آل عِمران /

Ẹsẹ 39

3 : 39
آل عِمران Àwọn Ẹsẹ 200
3 : 39

فَنَادَتۡهُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَهُوَ قَآئِمٞ يُصَلِّي فِي ٱلۡمِحۡرَابِ أَنَّ ٱللَّهَ يُبَشِّرُكَ بِيَحۡيَىٰ مُصَدِّقَۢا بِكَلِمَةٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَسَيِّدٗا وَحَصُورٗا وَنَبِيّٗا مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ

Nítorí náà, àwọn mọlāika pè é nígbà tí ó ń kírun lọ́wọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, (wọ́n sọ pé): “Dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú nípa (bíbí) Yahyā. Ó máa fi òdodo rinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu. (Ó máa jẹ́) aṣíwájú, tí kò kúndùn obìnrin. (Ó máa jẹ́) Ànábì. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere.”

Explanation & meanings · 2
  1. “Ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu”, ìyẹn ni pé, ẹni tí Allāhu fi "kunfayakun" ṣẹ̀dá rẹ̀.
  2. tàbí ẹni tí kò ju ẹ̀mí ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ìfẹ́-inú àti yòdòyìndìn ayé.