Skip to content
آل عِمران /

Ẹsẹ 156

3 : 156

Ẹsẹ 156 of آل عِمران (3 : 156). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

آل عِمران Àwọn Ẹsẹ 200
3 : 156

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَقَالُواْ لِإِخۡوَٰنِهِمۡ إِذَا ضَرَبُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ أَوۡ كَانُواْ غُزّٗى لَّوۡ كَانُواْ عِندَنَا مَا مَاتُواْ وَمَا قُتِلُواْ لِيَجۡعَلَ ٱللَّهُ ذَٰلِكَ حَسۡرَةٗ فِي قُلُوبِهِمۡۗ وَٱللَّهُ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe dà bí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sọ fún àwọn ọmọ ìyá wọn, nígbà tí wọ́n ń rìn kiri ní orí ilẹ̀ tàbí (nígbà) tí wọ́n ń jagun, pé: “Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wa ni, wọn ìbá tí kú, àti pé wọn ìbá tí pa wọ́n.” (Wọ́n wí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè fi ìyẹn ṣe àbámọ̀ sínú ọkàn wọn. Allāhu l’Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Explanation & meanings · 1
  1. Wọ́n ń rìn kiri ní orí ilẹ̀ láti wá ìjẹ-ìmu wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.