Skip to content
آل عِمران /

Ẹsẹ 140

3 : 140

Ẹsẹ 140 of آل عِمران (3 : 140). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

آل عِمران Àwọn Ẹsẹ 200
3 : 140

إِن يَمۡسَسۡكُمۡ قَرۡحٞ فَقَدۡ مَسَّ ٱلۡقَوۡمَ قَرۡحٞ مِّثۡلُهُۥۚ وَتِلۡكَ ٱلۡأَيَّامُ نُدَاوِلُهَا بَيۡنَ ٱلنَّاسِ وَلِيَعۡلَمَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَيَتَّخِذَ مِنكُمۡ شُهَدَآءَۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ ٱلظَّٰلِمِينَ

Tí ìpalára kan bá kàn yín, irú ìpalára bẹ́ẹ̀ kúkú ti kan ìjọ (kèfèrí) náà. Àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, À ń yí i po láààrin àwọn ènìyàn ni. Àti pé nítorí kí Allāhu lè ṣe àfihàn àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti (nítorí) kí Ó lè sọ àwọn kan nínú yín di òkú ojú-ogun (ní ojú-ọ̀nà Rẹ̀). Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí.

Explanation & meanings · 1
  1. Àádọ́rin àwọn Sọhābah - kí Allāhu yọ́nú sí wọn - ló bá ogun yìí lọ. Mẹ́rin nínú wọn jẹ́ muhājirūn. Hamzah ọmọ ‘Abdul-Muttọlib wà nínú wọn. Àwọn yòókù jẹ́ ansọ̄r - kí Allāhu yọ́nú sí gbogbo wọn -.