Skip to content
إبراهِيم /

Ẹsẹ 9

14 : 9

Ẹsẹ 9 of إبراهِيم (14 : 9). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

إبراهِيم Àwọn Ẹsẹ 52
Súrà · إبراهِيم
Yorùbá · Mikail
14 : 9

أَلَمۡ يَأۡتِكُمۡ نَبَؤُاْ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ قَوۡمِ نُوحٖ وَعَادٖ وَثَمُودَ وَٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ لَا يَعۡلَمُهُمۡ إِلَّا ٱللَّهُۚ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَرَدُّوٓاْ أَيۡدِيَهُمۡ فِيٓ أَفۡوَٰهِهِمۡ وَقَالُوٓاْ إِنَّا كَفَرۡنَا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ وَإِنَّا لَفِي شَكّٖ مِّمَّا تَدۡعُونَنَآ إِلَيۡهِ مُرِيبٖ

Ṣé ìró àwọn tó ṣíwájú yín kò tí ì dé ba yín ni? Ìjọ (Ànábì) Nūh, ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd àti àwọn tó wá lẹ́yìn wọn; kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Allāhu. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Nígbà náà, wọ́n dá ọwọ́ wọn padà sí ẹnu wọn, wọ́n sì wí pé: “Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú n̄ǹkan tí wọ́n fi ran yín níṣẹ́. Àti pé dájúdájú àwa wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí.”

Explanation & meanings · 1
  1. Bí àpẹ̀ẹrẹ kí ẹnì kan káwọ́ rẹ̀ méjèèjì sẹ́nu láti hu sí ẹnì kan nínú igbó.