Skip to content

“Ẹni tí ó bá fẹ́ ki wọn gbòòrò arisiki fun oun, ti o si fẹ ki ẹmi oun gùn, ki o maa da ẹbí pọ”.

Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:

“Ẹni tí ó bá fẹ́ ki wọn gbòòrò arisiki fun oun, ti o si fẹ ki ẹmi oun gùn, ki o maa da ẹbí pọ”.

«مَنْ أَحَبَّ أَنْ يُبْسَطَ لَهُ فِي رِزْقِهِ، وَيُنْسَأَ لَهُ فِي أَثَرِهِ، فَلْيَصِلْ رَحِمَهُ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣeni lojukokoro lati maa da ẹbí pọ pẹ̀lú abẹwo ati apọnle ti ara ati ti owó, ati nǹkan ti o yatọ si i, oun si tun ni okùnfà gbígbòòrò arisiki ati ẹmi gígùn.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ar-Rọhim ni àwọn mọlẹbi ni igun ti bàbá ati iya, bi o ba ṣe sunmọ si naa ni o ṣe ni ẹtọ láti da a pọ̀ tó.

Ẹsan maa wa latara iran iṣẹ ni, ẹni tí ó bá da ẹbí rẹ pọ pẹ̀lú dáadáa, Ọlọhun maa da a pọ̀ nibi ọjọ́-orí rẹ ati arisiki rẹ.

Dida ẹbí pọ jẹ okùnfà gbígbòòrò arisiki ati ẹmi gígùn, bi o tilẹ̀ jẹ́ pé àsìkò ti èèyàn maa lò laye ati arisiki ti ni gbèdéke, ṣùgbọ́n o tun le jẹ ìbùkún nibi arisiki ati ọjọ́-orí, o maa wa fi ìgbésí ayé rẹ ṣe nǹkan ti o maa pọ ti o si maa ṣe àǹfààní ju nǹkan ti ẹlòmíràn maa ṣe lọ, àwọn kan sọ pé alekun arisiki ati ọjọ́-orí naa maa jẹ alekun gidi. Ọlọhun ni O ni imọ julọ.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (8/ 5) (5986).

Tira Sọhiihu ti Muslim (4/ 1982) (2557).

Àlékún (10)

توضيح الأحكام من بلوغ المرام.

للبسام (7/ 320).

شرح رياض الصالحين.

لابن عثيمين (3/ 188).

فتح ذي الجلال والإكرام شرح بلوغ المرام.

لابن عثيمين (6/ 275).

تطريز رياض الصالحين.

لفيصل المبارك (ص224).

منحة العلام في شرح بلوغ المرام.

لعبد الله الفوزان (10/ 81).