Skip to content

“Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”.

Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:

“Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”.

«يَسِّرُوا وَلَا تُعَسِّرُوا، وَبَشِّرُوا وَلَا تُنَفِّرُوا».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ ki a maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ki a si ma fi ara ni wọn nibi gbogbo àlámọ̀rí ẹsin ati ayé, ìyẹn nibi ààlà nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni ẹtọ ti O si ṣe ni ofin. O n ṣeni lojukokoro lati maa fun wọn ni iro ìdùnnú nipa oore, ki a si ma le wọn sa kuro nibẹ.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ojuṣe onigbagbọ ododo ni ki o jẹ ki awọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun, ki o si maa ṣe wọn ni ojúkòkòrò lati ṣe rere.

O tọ́ fun olupepe si ọdọ Ọlọhun ki o fi ọgbọ́n wo ọ̀nà ti yoo gba mu ipepe Isilaamu de ọdọ àwọn èèyàn.

Ifunni ni iro ìdùnnú maa n bi ìdùnnú ati ìkọjúsí ati ifọkanbalẹ fun olupepe ati fun nǹkan ti o n fi han àwọn èèyàn.

Ifi-ara-ni àwọn èèyàn maa n bi sísá, ati ìkọ̀yìnsí, ati mimu àwọn èèyàn maa ṣe iyèméjì nibi ọ̀rọ̀ olupepe.

Gbígbòòrò aanu Ọlọhun fun awọn ẹru Rẹ, ati pe O yọnu si ẹsin kan ti o rọrùn fun wọn, ati ofin ti wọn ṣe ni irọrun.

Ṣíṣe idẹkun ti wọn pàṣẹ rẹ naa ni ohun ti sharia mu wá.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (1/ 25) (69).

Tira Sọhiihu ti Muslim (3/ 1358) (1732).

Àlékún (6)

شرح صحيح البخاري.

لابن بطال (1/ 153).

إرشاد الساري لشرح صحيح البخاري.

لأبو العباس القسطلاني (1/ 169).

بهجة الناظرين شرح رياض الصالحين.

لسليم الهلالي (1/ 687).