«Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa».
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amri – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe:
«Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa».
«الرَّاحِمُونَ يَرْحَمُهمُ الرَّحمنُ، ارحَمُوا أهلَ الأرضِ يَرْحْمْكُم مَن في السّماء».
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n ṣe alaye pe dajudaju awọn ti wọn maa n kẹ awọn ti wọn yatọ si wọn, Ọba Ajọkẹ aye naa o kẹ wọn pẹlu ikẹ Rẹ ti o kari gbogbo nkan; ní ti ẹ̀san t’ó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn). Lẹyin naa ni o wa pa aṣẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pẹlu kikẹ gbogbo nkan ti o wa lori ilẹ ni eeyan tabi ẹranko tabi ẹyẹ tabi nkan ti o yatọ si i ninu awọn iran ẹda, ati pe ẹsan iyẹn naa ni ki Ọlọhun kẹ wọn lati oke awọn sanmọ Rẹ.
...:
Ẹsin Isilaamu ẹ̀sìn ikẹ ni, ti gbogbo rẹ si duro lori itẹle aṣẹ Ọlọhun ati ṣiṣe daadaa si ẹda.
Ọlọhun – ti O tobi ti O gbọnngbọn - Ọba ti O ni ìròyìn ikẹ lara ni, ati pe Oun – mimọ fun un – ni Ajọkẹ aye Aṣakẹ orun, ti O si maa n mu ikẹ de ọdọ awọn ẹru Rẹ.
Iru iṣẹ ti eeyan ba ṣe naa ni ẹsan ti yio gba, nitori naa awọn ti wọn ba maa n kẹ eeyan Ọlọhun a kẹ awọn naa.
Tira Sunanu ti baba Daud (7/ 297) (4941).
Tira Sunanu ti Tirmidhiy (3/ 483) (1924).
Àlékún (7)
مسند أحمد ط الرسالة (11/ 33) (6494).
تحفة الأحوذي بشرح جامع الترمذي.
لمحمد المباركفورى (6/ 43).
سلسلة الأحاديث الصحيحة وشيء من فقهها وفوائدها.
للألباني (2/ 594).
معارج القبول بشرح سلم الوصول إلى علم الأصول.
حافظ الحكمي (1/ 156).