Skip to content

"Nnkan kan ko nii ṣẹlẹ̀ si Musulumi ninu wahala ati aisan ati ironu ati ibanujẹ ati suta ati ironu ati ki ẹgun gun un afi ki Ọlọhun ba a fi pa awọn aṣiṣe rẹ rẹ".

Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy ati lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:

"Nnkan kan ko nii ṣẹlẹ̀ si Musulumi ninu wahala ati aisan ati ironu ati ibanujẹ ati suta ati ironu ati ki ẹgun gun un afi ki Ọlọhun ba a fi pa awọn aṣiṣe rẹ rẹ".

«مَا يُصِيبُ الْمُسْلِمَ مِنْ نَصَبٍ وَلَا وَصَبٍ وَلَا هَمٍّ وَلَا حُزْنٍ وَلَا أَذًى وَلَا غَمٍّ حَتَّى الشَّوْكَةِ يُشَاكُهَا إِلَّا كَفَّرَ اللهُ بِهَا مِنْ خَطَايَاهُ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ohunkóhun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí Mùsùlùmí, bii aisan ati ironu ati ibanujẹ ati ajalu ati ile koko ati ipaya ati ebi- koda ki o jẹ ẹgun ni o gun un ti o wa n ko inira ba a-, ìyẹn maa jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun awọn ẹṣẹ rẹ ati awọn aṣiṣe rẹ.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

نصب: التعب.

وصب: المرض .

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Alaye ọla ti o n bẹ fun Ọlọhun lori awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ati ikẹ Rẹ pẹlu wọn pẹlu iforijin awọn ẹṣẹ wọn pẹlu eyi ti o kere julọ ninu inira ti o ba ṣẹlẹ̀ si wọn.

O tọ fun Musulumi lati maa reti ẹsan nnkan ti o ṣẹlẹ̀ si i lọdọ Ọlọhun, ki o si ṣe suuru lori gbogbo nnkan kekere ati ńlá, ki agbega ninu awọn ipo le jẹ tirẹ ati ipa awọn aburu rẹ.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (7/ 114) (5641).

Tira Sọhiihu ti Muslim (4/ 1992) (2572).

Àlékún (11)

كنوز رياض الصالحين.

لمجموعة من الباحثين (1/ 489).

شرح رياض الصالحين.

لابن عثيمين (1/ 242).

شرح النووي على مسلم (16/ 126).

تطريز رياض الصالحين.

لفيصل آل مبارك (ص44).

بهجة الناظرين شرح رياض الصالحين.

لسليم الهلالي (1/ 96).

نزهة المتقين شرح رياض الصالحين.

لمصطفى الخِن وغيره (1/ 70).