«Ṣe ẹnikọọkan yin o maa bẹru - tabi: Ẹnikọọkan yin o bẹru - nigba ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju imaamu, ki Ọlọhun o sọ ori rẹ di ori Kẹtẹkẹtẹ, tabi ki o sọ aworan di aworan Kẹtẹkẹtẹ».
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Ṣe ẹnikọọkan yin o maa bẹru - tabi: Ẹnikọọkan yin o bẹru - nigba ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju imaamu, ki Ọlọhun o sọ ori rẹ di ori Kẹtẹkẹtẹ, tabi ki o sọ aworan di aworan Kẹtẹkẹtẹ».
«أَمَا يَخْشَى أَحَدُكُمْ - أَوْ: لاَ يَخْشَى أَحَدُكُمْ - إِذَا رَفَعَ رَأْسَهُ قَبْلَ الإِمَامِ، أَنْ يَجْعَلَ اللَّهُ رَأْسَهُ رَأْسَ حِمَارٍ، أَوْ يَجْعَلَ اللَّهُ صُورَتَهُ صُورَةَ حِمَارٍ».
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye adehun iya ti o le gidi fun ẹni ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju imaamu rẹ, pẹlu pe ki Ọlọhun o sọ ori rẹ di ori Kẹtẹkẹtẹ, tabi ki o sọ aworan rẹ di aworan Kẹtẹkẹtẹ.
...:
O n bẹ fun ero ẹyin pẹlu imaamu rẹ ìṣesí mẹẹrin: Wọn kọ kuro nibi mẹta, oun naa ni: Gbigba iwaju ati biba dọgba ati pipẹ lẹyin, ati pe eyi ti wọn ṣe lofin fun ero ẹyin ni: Titẹle imaamu.
Jijẹ dandan itẹle ero ẹyin fun imaamu rẹ ninu irun.
Adehun iya pẹlu yiyi aworan ẹni ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju Imaamu sí aworan Kẹtẹkẹtẹ nkan ti o rọrun ni, oun si wa ninu pipa aworan da.
Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (1/ 140) (691).
Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 321) (427).
Àlékún (6)
الإلمام بشرح عمدة الأحكام.
لإسماعيل الأنصاري (1/ 111).
خلاصة الكلام شرح عمدة الأحكام.
لفيصل آل مبارك (ص65).
تيسير العلام شرح عمدة الأحكام.
للبسام (ص133).