Skip to content

«Ti ẹnikẹni ninu yin ba ri nkankan ninu ikun rẹ, ti o wa ru u loju boya nkankan jade nibẹ tabi ko jade, ki o ma ṣe jade kuro ni masalaasi titi ti yio fi gbọ ohun, tabi ki o gbọ oorun».

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:

«Ti ẹnikẹni ninu yin ba ri nkankan ninu ikun rẹ, ti o wa ru u loju boya nkankan jade nibẹ tabi ko jade, ki o ma ṣe jade kuro ni masalaasi titi ti yio fi gbọ ohun, tabi ki o gbọ oorun».

«إِذَا وَجَدَ أَحَدُكُمْ فِي بَطْنِهِ شَيْئًا، فَأَشْكَلَ عَلَيْهِ أَخَرَجَ مِنْهُ شَيْءٌ أَمْ لَا، فَلَا يَخْرُجَنَّ مِنَ الْمَسْجِدِ حَتَّى يَسْمَعَ صَوْتًا، أَوْ يَجِدَ رِيحًا».

Muslim ni ọ gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ti nkankan ba n ru ninu iku ẹni ti n kirun, ti ko wa mọ boya nkan jade tabi nkankan o jade? Ko gbọdọ kuro ni ori irun, ko si gbọdọ ja a lati lọ tun aluwala ṣe, titi ti yio fi ri bibẹ ẹgbin ni aridaju eleyii ti o le ba aluwala jẹ; pẹlu pe ki o gbọ didun iso, tabi ki o gbọ oorun; tori pe dajudaju nkan ti a ti mọ amọdaju rẹ ko lee yẹ pẹlu iyemeji, ati pe oun ti mọ amọdaju imọra, ti ẹgbin si jẹ nkan ti n ṣe iyemeji ninu rẹ.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Hadīth yii ipilẹ kan ni ninu awọn ipilẹ Isilaamu, o tun jẹ òfin kan ninu awọn ofin agbọye ẹsin, oun ni pe: Dajudaju amọdaju ko lee yẹ pẹlu iyemeji, ati pe ipilẹ ni wiwa nkan ti o n bẹ lori ohun ti o n bẹ lori rẹ, titi ti nkan ti o yatọ si iyẹn fi maa daju.

Iyemeji o ki n lapa nibi imọra, ati pe ẹni ti n kirun si wa lori imọra rẹ lopin igba ti ko ba tii ni amọdaju ẹgbin.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 276) (362).

Àlékún (2)

البحر المحيط الثجاج في شرح صحيح الإمام مسلم بن الحجاج (8/ 374).

المفهم لما أشكل من تلخيص كتاب مسلم (1/ 608).