6 : 60
وَهُوَ ٱلَّذِي يَتَوَفَّىٰكُم بِٱلَّيۡلِ وَيَعۡلَمُ مَا جَرَحۡتُم بِٱلنَّهَارِ ثُمَّ يَبۡعَثُكُمۡ فِيهِ لِيُقۡضَىٰٓ أَجَلٞ مُّسَمّٗىۖ ثُمَّ إِلَيۡهِ مَرۡجِعُكُمۡ ثُمَّ يُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Òun ni Ẹni tó ń kùn yín ní oorun ní alẹ́. Ó sì nímọ̀ nípa ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́ ní ọ̀sán. Lẹ́yìn náà, Ó ń gbe yín dìde (fún ìjẹ-ìmu) ní (ọ̀sán) nítorí kí wọ́n lè parí gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí yín. Lẹ́yìn náà, Ó máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Explanation & meanings · 1
- Ismul-mọsdar “yatawaffākum” ni “wafāt”. Ní àyè yìí “wafāt” kò sì túmọ̀ sí ikú bí kò ṣe oorun. Bákan náà, “wafāt” ni ismul-mọsdar “tawaffat-hu” nínú āyah 61 níwájú. Òhun sì túmọ̀ sí ikú.