Skip to content
الأنعَام /

Ẹsẹ 139

6 : 139
الأنعَام Àwọn Ẹsẹ 165
Súrà · الأنعَام
Yorùbá · Mikail
6 : 139

وَقَالُواْ مَا فِي بُطُونِ هَٰذِهِ ٱلۡأَنۡعَٰمِ خَالِصَةٞ لِّذُكُورِنَا وَمُحَرَّمٌ عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِنَاۖ وَإِن يَكُن مَّيۡتَةٗ فَهُمۡ فِيهِ شُرَكَآءُۚ سَيَجۡزِيهِمۡ وَصۡفَهُمۡۚ إِنَّهُۥ حَكِيمٌ عَلِيمٞ

Wọ́n tún wí pé: “Ohun tí ń bẹ nínú ikùn àwọn ẹran-ọ̀sìn wọ̀nyí jẹ́ ti àwọn ọkùnrin wa nìkan, ó sì jẹ́ èèwọ̀ fún àwọn obìnrin wa.” Tí ó bá sì jẹ́ òkú ọmọ-ẹran, akẹgbẹ́ sì ni wọn nínú (ìpín) rẹ̀. (Allāhu) yóò san wọ́n ní ẹ̀san irọ́ (ẹnu) wọn. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

Explanation & meanings · 1
  1. Ìyẹn ni pé, bí ẹran-ọ̀sìn wọn bá bí ọlẹ̀ rẹ̀ ní ààyè, ọmọ ẹran náà máa jẹ́ ti ọkùnrin nìkan, wọn kò sì níí jẹ́ kí obìnrin ní ìpín kan nínú rẹ̀. Bí ó bá jẹ́ òkúmọ, ọkùnrin àti obìnrin sì dìjọ máa pín in.