Skip to content
المُجَادلة /

Ẹsẹ 2

58 : 2
المُجَادلة Àwọn Ẹsẹ 22
58 : 2

ٱلَّذِينَ يُظَٰهِرُونَ مِنكُم مِّن نِّسَآئِهِم مَّا هُنَّ أُمَّهَٰتِهِمۡۖ إِنۡ أُمَّهَٰتُهُمۡ إِلَّا ٱلَّٰٓـِٔي وَلَدۡنَهُمۡۚ وَإِنَّهُمۡ لَيَقُولُونَ مُنكَرٗا مِّنَ ٱلۡقَوۡلِ وَزُورٗاۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَعَفُوٌّ غَفُورٞ

Àwọn tó ń fi ẹ̀yìn ìyàwó wọn wé ti ìyá wọn nínú yín, àwọn ìyàwó kì í ṣe ìyá wọn. Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ìyá wọn bí kò ṣe ìyá tí ó bí wọn lọ́mọ. Dájúdájú wọ́n ń sọ aburú nínú ọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ irọ́. Dájúdájú Allāhu ni Alámòójúkúrò, Aláforíjìn.

Explanation & meanings · 1
  1. Kíyè sí i, òfin tó ṣe é ní èèwọ̀ fún ọkọ láti fi ẹ̀yìn ìyàwó rẹ̀ wé ẹ̀yìn ìyá rẹ̀, òfin náà l’ó ṣe é ní èèwọ̀ fún un láti fi wé ẹ̀yìn ìyá tó fún un ní ọyàn mú ní kékeré nígbà tí kò tí ì já l’ẹ́nu ọyàn.