47 : 30
وَلَوۡ نَشَآءُ لَأَرَيۡنَٰكَهُمۡ فَلَعَرَفۡتَهُم بِسِيمَٰهُمۡۚ وَلَتَعۡرِفَنَّهُمۡ فِي لَحۡنِ ٱلۡقَوۡلِۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ أَعۡمَٰلَكُمۡ
Àti pé tí A bá fẹ́ Àwa ìbá fi wọ́n hàn ọ́, ìwọ ìbá sì mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Dájúdájú ìwọ yóò mọ̀ wọ́n níbi pé wọ́n máa ń pẹ́kọrọ ọ̀rọ̀. Allāhu sì mọ àwọn iṣẹ́ (ọwọ́) yín.
Explanation & meanings · 1
- Ìyẹn ni pé, àwọn aláìsàn-ọkàn máa ń pẹ́kọrọ nínú ìsọ̀rọ̀ wọn. Wọn kò sì níí rìn sàn-án lórí ọ̀rọ̀ nítorí àbòsí ọwọ́ wọn sì ni.