Skip to content
الزُّخرُف /

Ẹsẹ 45

43 : 45
الزُّخرُف Àwọn Ẹsẹ 89
43 : 45

وَسۡـَٔلۡ مَنۡ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رُّسُلِنَآ أَجَعَلۡنَا مِن دُونِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ءَالِهَةٗ يُعۡبَدُونَ

Bèèrè wò lọ́wọ́ àwọn tí A rán níṣẹ́ ṣíwájú rẹ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa (pé): “Ǹjẹ́ A sọ àwọn kan di ọlọ́hun tí wọn yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé bí?”

Explanation & meanings · 1
  1. Àgbọ́yé kìíní ni pé, ìbéèrè náà wáyé nínú ìrìn-àjò òru àti ìgun-sánmọ̀ tí Allāhu mú Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rìn. Àgbọ́yé kejì ni pé, ìbéèrè náà wáyé láààrin Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti àwọn tó nímọ̀ nípa Taorāt àti ’Injīl. Ìyẹn ni pé, kí ni àwọn tírà méjèèjì sọ nípa “ta ni a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, ṣé Allāhu ni tàbí àwọn ọlọ́hun mìíràn?”