Skip to content
غَافِر /

Ẹsẹ 15

40 : 15
غَافِر Àwọn Ẹsẹ 85
Súrà · غَافِر
Yorùbá · Mikail
40 : 15

رَفِيعُ ٱلدَّرَجَٰتِ ذُو ٱلۡعَرۡشِ يُلۡقِي ٱلرُّوحَ مِنۡ أَمۡرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦ لِيُنذِرَ يَوۡمَ ٱلتَّلَاقِ

(Allāhu) Ẹni tó ni gbogbo ipò àjùlọ, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, Ó ń fi ìmísí mímọ́ ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorì kí ó lè fi ṣèkìlọ̀ nípa Ọjọ́ ìpàdé náà.

Explanation & meanings · 1
  1. Kíyè sí n̄ǹkan kan tó lágbára nínú āyah yìí nítorí kí o má baà di kèfèrí. Gbólóhùn yìí, “Ó ń fi ìmísí mímọ́ ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni = = tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀”, ìṣe yìí ti dópin nípasẹ̀ bí Allāhu ti ṣe fi Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe òpin gbogbo àwọn tí ó gba ìmísí mímọ́ náà. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-’Ahzāb; 33:40. Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tún sọ pé, òun náà wà nínú ẹni tí Allāhu fẹ́ fún rírí ìmísí mímọ́ gbà, òpùrọ́ asòòkùn sẹ́sìn ni onítọ̀ún.