17 : 107
قُلۡ ءَامِنُواْ بِهِۦٓ أَوۡ لَا تُؤۡمِنُوٓاْۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ مِن قَبۡلِهِۦٓ إِذَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ يَخِرُّونَۤ لِلۡأَذۡقَانِۤ سُجَّدٗاۤ
Sọ pé: “Ẹ gbàgbọ́ nínú al-Ƙur’ān tàbí ẹ kò gbàgbọ́ nínú rẹ̀, dájúdájú àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ṣíwájú (ìsọ̀kalẹ̀) rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀, tí wọ́n yóò forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).