14 : 4
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن رَّسُولٍ إِلَّا بِلِسَانِ قَوۡمِهِۦ لِيُبَيِّنَ لَهُمۡۖ فَيُضِلُّ ٱللَّهُ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
A kò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi pẹ̀lú èdè àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣàlàyé (ẹ̀sìn) fún wọn. Nígbà náà, Allāhu yóò ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà; Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Explanation & meanings · 2
- “Lisān” (ahọ́n) dúró fún “èdè” nínú āyah yìí. Ẹ tún wo “lisān” nínú sūrah an-Nahl; 16:103.
- Ìyẹn ni pé, èdè wáhàyí Ànábì kọ̀ọ̀kan ni èdè àwọn ènìyàn rẹ̀.