Skip to content
يُوسُف /

Ẹsẹ 88

12 : 88
يُوسُف Àwọn Ẹsẹ 111
Súrà · يُوسُف
Yorùbá · Mikail
12 : 88

فَلَمَّا دَخَلُواْ عَلَيۡهِ قَالُواْ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡعَزِيزُ مَسَّنَا وَأَهۡلَنَا ٱلضُّرُّ وَجِئۡنَا بِبِضَٰعَةٖ مُّزۡجَىٰةٖ فَأَوۡفِ لَنَا ٱلۡكَيۡلَ وَتَصَدَّقۡ عَلَيۡنَآۖ إِنَّ ٱللَّهَ يَجۡزِي ٱلۡمُتَصَدِّقِينَ

Nìgbà tí wọ́n wọlé tọ Yūsuf, wọ́n sọ pé: “Ìwọ ọba, ìnira (ebi) ti mú àwa àti ará ilé wa. A sì mú owó kan tí ẹ máa ta dànù lọ́wọ́. Nítorí náà, wọn kóńgò (oúnjẹ) náà kún fún wa, kí ó sì ta wá lọ́rẹ. Dájúdájú Allāhu yóò san àwọn olùtọrẹ ní ẹ̀san rere.”

Explanation & meanings · 1
  1. Ìyẹn ni pé, owó tí wọ́n mú dání kì í ṣe owó tí wọ́n lè gbà lọ́wọ́ wọn torí pé ó kéré púpọ̀, tàbí owó náà ti fẹ́ di kọ̀ǹdẹ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́.