Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

29 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
“Ẹni tí ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe sàárà gbanngba, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe saara kọ̀kọ̀”.
O ni alaafia Baba Daud ati Tirmisiy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa
"Ṣé ki n fun yin ni iro nipa eyi ti o daa julọ ninu awọn iṣẹ yín, ati eyi ti o mọ julọ ninu rẹ lọdọ Oluwa yin, ati eyi ti o ga julọ ninu rẹ ninu awọn ipo yin ti o si loore julọ fun yin ju nina wura ati fadaka lọ, ti o si loore julọ fun yin ju ki ẹ pade ọta yin ki ẹ si ge awọn ọrun wọn ki wọn si ge ọrun yin lọ? Wọn sọ pé: Bẹẹni. O sọ pe: "Iranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-".
O ni alaafia Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
A jade ni alẹ ọjọ kan ti ojo n rọ ti o si ṣokunkun gidigidi, ti a n wa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a; lati kirun fun wa, o sọ pe: Ni a ba ri i, ni o wa sọ pe: «Sọ», mi o si sọ nkankan, lẹyin naa o sọ pe: «Sọ», mi ò si sọ nkankan, o sọ pe: «Sọ», ni mo ba sọ pe: Kini maa sọ? O sọ pe: «{Qul Uwal Laahu ahad} ati Al-mu‘awwidhatayn (Falaqi ati Naasi) nigba ti o ba di irọlẹ ati ti o ba di afẹmọjumọ ni igba mẹta, yio to ọ nibi gbogbo nkan».
O ni alaafia Baba Daud ati Tirmisiy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa
Mo lọ ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe mọ fẹ gba Isilaamu, o wa pa mi láṣẹ lati wẹ pẹlu omi ati ewe sidiru.
O ni alaafia Baba Daud ati Tirmisiy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa
“Ẹni ti o ba dáàbò bo iyì ọmọ-ìyá rẹ, Ọlọhun maa dáàbò bo ojú rẹ kuro nibi iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”.
O ni alaafia Tirmisiy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba sin, o maa n gbe ọwọ rẹ- tabi aṣọ rẹ- si ẹnu rẹ, ti o maa fi rẹ ohun rẹ nilẹ.
O ni alaafia Baba Daud ati Tirmisiy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
“Ẹni ti o ba lọ onigbese lára, tabi ti o ba a din in ku tabi ki o ni ki o ma san an mọ́, Ọlọhun maa fi i sábẹ́ ibòji Ìtẹ́-ọlá Rẹ̀ ni Ọjọ́ Àjíǹde, ni ọjọ́ ti ko nii si ibòji kankan àyàfi ibòji Rẹ̀”.
O ni alaafia Tirmisiy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
"Ẹ tẹti ẹ gbọ, o ṣee ṣe ki arakunrin kan, ki hadisi nipa mi de etigbọọ rẹ ti o si rọgbọku ni ori ibusun rẹ, ki o wa maa sọ pe: Iwe Ọlọhun n bẹ laaarin wa ati yin, nǹkan ti a ba ri nibẹ ni ẹtọ a maa ṣe e ni ẹtọ, nnkan ti a ba si ri nibẹ ni eewọ a maa ṣe e ni eewọ. Ati pe dajudaju nnkan ti Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ṣe ni eewọ da gẹgẹ bii nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ".
O ni alaafia Baba Daud ati Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ni wọn gba a wa