Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

30 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
«Ko si ẹnìkankan ti yio da ẹṣẹ kan, lẹyin naa ni o wa dide ti o si ṣe imọra, lẹyin naa ni o wa kirun, lẹyin naa o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun ṣe aforijin fun un», lẹyin naa ni o wa ka aaya yii: {Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn} [Āl ‘Imraan: 135].
O ni alaafia Baba Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú tira al-Kubrọh , ati Ọmọ Maajah ati Ahmad
“Ko si igbeyawo kan afi pẹlu alaṣẹ obinrin”.
O ni alaafia Baba Daud ati Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ati Ahmad ni ọ gba a wa
“Ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ latara ìràwọ̀, onítọ̀hún ti gba ẹka kan ninu oògùn, bi o ba ṣe n lekun ninu imọ ìràwọ̀ naa ni kikọ oògùn rẹ naa ṣe maa lékún”.
O ni alaafia Baba Daud ati Ọmọ Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni àárọ̀ jiju okuta ipari, ti o si wa lori rakunmi rẹ pé: "Ba mi mu okuta kekere kan" mo wa mu awọn okuta kekere meje fun un, awọn ni okuta kéékèèké tí a maa n fi ìka méjì jù, o wa bẹ̀rẹ̀ si nii ju wọn si atẹlẹwọ rẹ, o si n sọ pe: "Awọn iru awọn wọnyi ni ẹ maa ju" lẹyin naa o sọ pe: "Ẹyin eniyan, ẹ ṣọ́ra kuro nibi aṣeju nibi ẹsin, dajudaju nnkan ti o pa àwọn ti wọn ṣíwájú yin run ni aṣeju nibi ẹsin".
O ni alaafia Ọmọ Maajah ati Nasaa'iy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
"Ẹ bẹru Ọlọhun Oluwa yin, ẹ ki irun wakati marun-un yin, ẹ gba awẹ oṣu yin, ẹ yọ saka awọn dukia yin, ẹ tẹle adari àlámọ̀rí yin ẹ maa wọ alujanna Olúwa yín".
O ni alaafia Tirmisiy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
"Pákò jẹ́ imọtoto fun ẹnu, ó sì jẹ́ okunfa iyọnu Oluwa".
O ni alaafia Nasaa'iy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa nǹkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ alujanna julọ, o sọ pe: “Ìpayà Ọlọhun ati iwa dáadáa”, wọn tun bi i leere nipa nnkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ ina julọ, o sọ pe: “Ẹnu ati Abẹ”.
O daa, o si ni alaafia Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
“Ọlọhun fi àkàwé kan lélẹ̀ nipa ojú ọ̀nà tààrà kan, ti ògiri méjì wa ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ojú ọ̀nà naa, ti àwọn ẹnu ọ̀nà ti wọn ṣí silẹ wa nibẹ, ti àwọn aṣọ ẹnu ọ̀nà ti wọn dà wálẹ̀ si n bẹ ni àwọn ẹnu ọ̀nà naa, olupepe kan n bẹ ni ẹnu ọ̀nà ojú ọ̀nà naa ti n sọ pé: Ẹ̀yin èèyàn, gbogbo yin ẹ ko sínú ọ̀nà naa, ẹ má ṣe wọ́, ati olupepe kan ti n pepe lati òkè ọ̀nà naa, ti o ba ti wa fẹ ṣí nǹkan kan ninu awọn ojú ọ̀nà yẹn, o maa sọ pé: Káì, ma ṣi i, ti o ba fi le ṣi i wàá wọ̀ ọ́, ojú ọ̀nà naa ni Isilaamu, àwọn ògiri méjèèjì naa ni: Awọn ààlà Ọlọhun, àwọn ẹnu ọ̀nà ti wọn ṣi silẹ ni: Awọn nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ, ẹni tí n pepe ni orí ojú ọ̀nà naa ni: Tira Ọlọhun, ẹni tí n pepe ni òkè ojú ọ̀nà naa ni: Oníwàásù Ọlọhun ninu ọkàn gbogbo Musulumi”.
O ni alaafia Tirmisiy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa