Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

6 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
“Dajudaju ninu awọn ami ọjọ igbende ni ki wọn ka imọ kúrò nílẹ̀, ki aimọkan si pọ, ki ṣina si pọ, ti ọti mimu si maa pọ, ti onka awọn ọkunrin si maa kere, ti onka awọn obinrin si maa pọ titi ti o fi maa jẹ pe ọkùnrin kan ni yoo maa bẹ fun aadọta obinrin”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Mu’aadh wa lẹ́yìn Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori nnkan ọgun, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh ọmọ Jabal”, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, o tun sọ pe: “Irẹ Mu’aadh”, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, lẹẹmẹta, o sọ pe: “Ko si ẹni kankan ti o n jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Allahu, ati pe Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni lododo lati inu ọkan rẹ, afi ki Ọlọhun ṣe ina leewọ fun un”, o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, njẹ mi ko nii maa sọ ọ fun awọn eniyan ki wọn le dunnu? O sọ pe: “Ti o ba ri bẹẹ wọn maa gbara le e”. Ni Mu’aadh wá sọ ọ́ nigba ti o fẹ ku ki o ma baa kó sínú ẹṣẹ.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
“Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
A wa ni ọdọ ‘Umar, o wa sọ pe: «Wọn kọ fun wa kuro nibi ifipaṣe-nnkan»
O ni alaafia Bukhaariy lọ gba a wa
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii da lọ́fíńdà padà.
O ni alaafia Bukhaariy lọ gba a wa
“Ẹni tí ó bá fẹ́ ki wọn gbòòrò arisiki fun oun, ti o si fẹ ki ẹmi oun gùn, ki o maa da ẹbí pọ”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni