Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

14 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
"Ẹ bẹru Ọlọhun Oluwa yin, ẹ ki irun wakati marun-un yin, ẹ gba awẹ oṣu yin, ẹ yọ saka awọn dukia yin, ẹ tẹle adari àlámọ̀rí yin ẹ maa wọ alujanna Olúwa yín".
O ni alaafia Tirmisiy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
“Mumini ti o pe jù ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dara ju, ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí o dara ju fun awọn obinrin wọn”.
O daa Baba Daud ati Tirmisiy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa nǹkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ alujanna julọ, o sọ pe: “Ìpayà Ọlọhun ati iwa dáadáa”, wọn tun bi i leere nipa nnkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ ina julọ, o sọ pe: “Ẹnu ati Abẹ”.
O daa, o si ni alaafia Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
“Adua naa ni ìjọsìn”, lẹyin naa ni o wa ka: “{Olúwa yín sọ pé: “Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ} [Gaafir: 60]”.
O ni alaafia Baba Daud ati Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ati Ahmad ni ọ gba a wa
“Ko si nǹkan kan ti o ni apọnle ni ọdọ Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga - ju adua lọ”
O daa Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
“Bí ọkùnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, kí ó sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀”.
O ni alaafia Baba Daud ati Tirmisiy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú tira al-Kubrọ, ati Ahmad