Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

13 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
Lati ọdọ Humraan ẹru Uthman ọmọ ‘Affan pé o ri Uthman ọmọ ‘Affan ti o beere fun omi aluwala, o ti ọwọ rẹ mejeeji bọ inu igba rẹ, o fọ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ ọtun bọ inu omi aluwala, lẹyin naa o fi omi yọ ẹnu rẹ o si fin in simu o si fin in síta, lẹyin naa o fọ oju rẹ lẹẹmẹta, ati ọwọ rẹ mejeeji titi de igunpa rẹ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o pa ori rẹ, lẹyin naa o fọ gbogbo ẹsẹ rẹ lẹẹmẹta, lẹyin naa o sọ pe: Mo ri Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yìí, o wa sọ pe: “Ẹni ti o ba ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yii lẹyin naa o wa ki rakah meji ti ko ba ẹmi rẹ sọrọ nibi mejeeji, Ọlọhun yoo fori nnkan ti o ṣíwájú ninu ẹṣẹ rẹ jin in”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
التصنيف الشرعيفضل الوضوء، صفة الوضوءموضوعات الحديثأحكام الوضوء، صلاة التطوع
“Ẹni ti o ba ṣe aluwala ti o si ṣe aluwala naa daadaa, awọn àṣìṣe rẹ maa jade kúrò lára rẹ titi yoo fi maa jade lati abẹ awọn èékánná rẹ”.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
التصنيف الشرعيفضل الوضوءموضوعات الحديثأحكام الوضوء
Dajudaju arakunrin kan ṣe aluwala ni o wa fi aaye eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ri i ti o si sọ pe: «Pada ki o si lọ ṣe aluwala rẹ daadaa» ni o ba pada, lẹyin naa ni o kirun.
O ni alaafia pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí rẹ Muslim ni ọ gba a wa
التصنيف الشرعيأركان الوضوء، صفة الوضوءموضوعات الحديثأحكام الوضوء
Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe aluwala lẹẹmeji meji.
O ni alaafia Bukhaariy lọ gba a wa
التصنيف الشرعيسنن وآداب الوضوء، صفة الوضوءموضوعات الحديثأحكام الوضوء
Mo ri ti Amru ọmọ Abu Hasan bi Abdullahi ọmọ Zaid leere nipa aluwala Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni o ba beere fun igba kan ti omi wa ninu ẹ, o ṣe aluwala fun wọn ni aluwala Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o da omi si ọwọ rẹ lati inu igba, o fọ ọwọ rẹ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ bọ inu igba, o fi omi yọ ẹnu o si fa a simu, O si fa a sita, ni gẹẹ mẹta, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ bọ ọ, o si fọ oju rẹ lẹẹmẹta, lẹyin naa o fọ ọwọ rẹ mejeeji ni ẹẹmeji titi de igunpa mejeeji, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ bọ ọ, o si pa ori rẹ, o gbe mejeeji lọ si ẹyin ati ṣíwájú ni ẹẹkan, lẹyin naa, o fọ ẹsẹ rẹ mejeeji titi de kokosẹ
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
التصنيف الشرعيصفة الوضوءموضوعات الحديثأحكام الوضوء