Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

105 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́

Olùgbàsọ

Fi gbogbo olùgbàsọ hàn (55)
“Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun lọ ti a ki ni ibi ti o yatọ si i afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Dajudaju maa fun arakunrin kan ni asia yii ni ọla ti Ọlọhun maa ti ipasẹ rẹ fun wa ni iṣẹgun, o nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ naa nífẹ̀ẹ́ rẹ”, o sọ pe: Àwọn ènìyàn sùn ní alẹ́ náà tí wọ́n ń jiroro laarin ara wọn tani wọn yoo fun.” Nígbà ti ilẹ̀ mọ́, àwọn èèyàn lọ ba ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti ọkọọkan ninu wọn si n fẹ ki wọn fun oun, o sọ pe: “Ibo ni ‘Ali ọmọ Abu Talib wà”? Wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ojú n dùn ún. O sọ pe: “Ẹ ranṣẹ si i”, wọn si mu u wa ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa tutọ́ si oju rẹ mejeeji, o si ṣe adura fun un, o si gbadun gẹgẹ bii pe inira kan kan ko mu u, o wa fun un ni asia náà. Ali wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki n maa ba wọn ja titi wọn fi maa da bii wa? O sọ pe: “Maa lọ ni pẹlẹpẹlẹ titi waa fi dé agbegbe wọn, lẹyin naa pe wọn sinu Isilaamu, sọ nnkan ti o jẹ dandan le wọn lori ninu ẹtọ Ọlọhun fun wọn nibẹ. Mo fi Ọlọhun bura, ki Ọlọhun fi arákùnrin kan ṣoṣo mọna latara rẹ, o loore fun ẹ ju ki o ni ràkúnmí pupa lọ".
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fẹ wẹ janaba, yio fọ ọwọ rẹ mejeeji, yio si tun ṣe aluwala rẹ ti maa n ṣe fun irun, lẹyin naa yio wẹ, lẹyin naa yio fi ọwọ rẹ mejeeji ya irun rẹ, titi ti yio fi ro ni ẹmi rẹ pe o ti kan awọ isalẹ irun rẹ, yio wa da omi si ara ni ẹẹmẹta, lẹyin naa yio wẹ ara rẹ yoku, ni o wa sọ pe: Mo jẹ ẹni ti emi pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - maa n wẹ papọ ninu igba kan náà, ti a si jọ maa n fi ọwọ bu omi papọ ninu rẹ.
O ni alaafia Bukhaariy lọ gba a wa
«Mumini o gbọdọ maa korira muminah, ti o ba korira iwa kan lara rẹ, yio yọnu si omiran lara rẹ» tabi o sọ pe: «Yatọ si i».
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jade si wa, a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a ti kọ bi a ṣe maa salamọ si ẹ, bawo ni a ṣe maa ṣe asalatu fun ẹ? o sọ pe: "Ẹ maa sọ pe: Allahumo solli 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa sollaita 'alaa aali Ibrahim, innaka Hamiidun Majeedun, Allahumo baarik 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa baarokta 'alaa aali Ibrahim, innaka Hamiidun Majeedun".
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni o wa lọ sibi akitan ijọ kan, ti o si tọ ni iduro, ni mo ba takete si i, o wa sọ pe: «Sunmọ ibi» ni mo ba sunmọ titi mo fi duro si ibi ẹyin gigirisẹ rẹ mejeeji, nigba naa ni o ṣe aluwala ti o si fi ọwọ pa ibọsẹ alawọ rẹ mejeeji.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n sọ laarin iforikanlẹ mejeeji pe: «Allāhummọ igfir li, warhamnī, wa ‘āfinī, wahdinī, warzuqnī».
O daa pẹlu awọn ẹri rẹ Baba Daud ati Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ati Ahmad ni ọ gba a wa
Nígbà tí a jokoo pẹlu Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nínú mọṣalaaṣi, ọkùnrin kan ba wọlé lórí ràkúnmí, o da ràkúnmí rẹ̀ gunlẹ, o si dè é, lẹ́yìn naa o sọ fún wọn pé: Èwo ni Muhammad nínú yin? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si rọ̀gbọ̀kú láàrin wọn, ni a wa sọ pé: Ọkunrin pupa ti o rọ̀gbọ̀kú yii ni. Arákùnrin naa wa sọ fún un pé: Irẹ ọmọ Abdul Muttọlib, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Mo ti da ẹ lóhùn”. Arákùnrin naa wa sọ fún Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Maa bi ọ léèrè, ti mo si ma le mọ́ ọ lori ìbéèrè naa, ma ṣe bínú sí mi. O wa sọ pe: “Bèèrè ohun ti o ba fẹ”, o wa sọ pé: Mo fi Oluwa rẹ bẹ ọ ati Olúwa àwọn ti wọn ṣiwaju rẹ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O ran ọ si gbogbo àwọn èèyàn? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa ki irun wákàtí márùn-ún ni ojúmọ́? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pé: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa gba aawẹ oṣù yii nínú ọdún? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki o gba sàká yii lọ́wọ́ àwọn olówó wa ki o si pin in fun awọn talika wa? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Bẹẹni”. Arákùnrin naa wa sọ pé: Mo gba ohun ti o mu wa gbọ́, èmi si ni ojiṣẹ fun awọn ijọ mi, emi ni Dimaam ọmọ Tha’labah, láti ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni