Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

104 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́

Olùgbàsọ

Fi gbogbo olùgbàsọ hàn (53)
«Dajudaju irun ti o wuwo ju fun awọn munaafiki ni irun Ishai ati Asunbaa, ka ni wọn mọ nkan ti n bẹ ninu rẹ - ni ẹsan – ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ ni irakoro, ati pe mo ti wa gbero lati paṣẹ ki wọn o gbe irun duro, lẹyin naa ki n wa pa ẹnikan laṣẹ ki o ki i, lẹyin naa ki n wa gbera pẹlu awọn ọkunrin kan ti idi igi wa pẹlu wọn lọ si ọdọ awọn ijọ kan ti wọn o ki n wa ki irun ni masalaasi, ki n si sun ile wọn mọ wọn lori».
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
«Ọlọhun a gba ilẹ mu, yoo si tun ka sanmọ pẹlu ọwọ ọtun Rẹ, lẹyin naa ni Yoo waa sọ pe: Emi ni Ọba, gbogbo ọba (olukapa) ori ilẹ̀ da?».
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ní o ku ọdún márùn-ún tí ó fi maa jáde láyé, ti o ń sọ wípé: “Dajudaju emi n bọpabọsẹ lọ si ọdọ Ọlọhun pe ki n ní ọrẹ aayo kan laarin yin, nitori pe Ọlọhun Ọba Aleke ọla ti mú mi ní ọrẹ aayo gẹgẹ bi O ti mu Ibrahim ni ọrẹ aayo, ti emi ba ti ẹ fẹ mu ẹnikan ninu awọn ijọ mi ni ọrẹ aayo, emi i ba mu Abu Bakr ni ọrẹ aayo, ẹ gbọ o, dajudaju awọn ijọ tí wọ́n ti lọ síwájú yin a maa mú saare awọn Anabi ati awọn ẹniire inu wọn ni mọṣalaṣi, nitori naa, ẹ má ṣe mú awọn saare ni mọṣalaṣi, dajudaju emi n kọ ọ fún yín”.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
Lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dajudaju o sọ nipa awọn Ansar pe: "Ẹnikan ko nii nífẹ̀ẹ́ wọn afi olugbagbọ, ẹnikan ko si nii korira wọn afi sobẹ-ṣelu, ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ wọn, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ".
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Nigba ti (Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem) sọkalẹ (At-Takathur: 8), Az-Zubair sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, idẹra wo ni wọn maa bi wa leere nipa rẹ, dajudaju mejeeji ni dudu meji, eso dabinu ati omi? O sọ pe: “Oun naa ni o maa jẹ”.
O daa Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ni ọ gba a wa
“Ẹni tí ó bá kó ìpalára ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìpalára ba oun naa, ẹni tí ó bá ko ìnira ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìnira ba oun naa”.
O daa Baba Daud ati Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ati Ahmad ni ọ gba a wa
“Dájúdájú Ọlọhun maa n lọ́ alabosi lára, titi ti yoo fi mu u ti ko si nii jẹ ki ó bọ́”, o sọ pe: Lẹ́yìn náà ni o ka: “{Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le} [Huud: 102]”
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: “Ọlọhun sọ pe: Ọmọ Adam pe Mi ni opurọ, ko si tọ fun un, o si bu mi, ko si tọ fun un, pipe ti o pe Mi ni opurọ ni ọrọ rẹ ti o sọ pe: Ko lee da mi pada gẹgẹ bi O ṣe da mi ni akọkọ, akọkọ ẹ̀dá ko si rọrùn fun mi ju dida a pada lọ, ṣùgbọ́n èébú tí ó bu Mi ni ọrọ rẹ ti o sọ pe: Ọlọhun ni ọmọ, Ọkan ṣi ni Mi, Ajironukan ni Mi, Mi o bímọ, wọn o si bi Mi, ko si si ẹni kan ti o jọ Mi".
O ni alaafia Bukhaariy lọ gba a wa