Skip to content

"Ọjọ igbedide ko nii to titi ti arakunrin o fi maa kọja nibi saare arakunrin, o maa sọ pé: Mii ba si wa ni ipo rẹ".

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:

"Ọjọ igbedide ko nii to titi ti arakunrin o fi maa kọja nibi saare arakunrin, o maa sọ pé: Mii ba si wa ni ipo rẹ".

«لاَ تَقُومُ السَّاعَةُ حَتَّى يَمُرَّ الرَّجُلُ بِقَبْرِ الرَّجُلِ فَيَقُولُ: يَا لَيْتَنِي مَكَانَهُ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ọjọ igbende ko nii to titi ti arakunrin maa fi kọja nibi saare ti yoo si maa gbero lati jẹ oku dipo rẹ, idi ni ibẹru rẹ lori ara rẹ nibi lilọ ẹsin rẹ pẹlu ibori ibajẹ ati awọn onibajẹ, ati hihan awọn fitina ati awọn ẹṣẹ ati awọn ibajẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Itọka pẹlu hihan awọn ẹṣẹ ati awọn wahala ni igbẹyin aye.

Ṣisẹnilojukokoro lori iṣọra ati igbaradi fun iku pẹlu igbagbọ ati awọn iṣẹ oloore, ati jijina si awọn aaye wahala ati adanwo.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (9/ 58) (7115).

Tira Sọhiihu ti Muslim (4/ 2231) (157).

Àlékún (4)

إكمال المعلم (8/451).

شرح ابن بطال (10/58).

الإفصاح عن معاني الصحاح (6/295).

البحر المحيط الثجاج في شرح صحيح الإمام مسلم بن الحجاج (44/ 388).